
Forex lè dún bí ohun tó ń páni lẹ́rù díẹ̀, ṣùgbọ́n ní òtítọ́, ó rọrùn láti wọ̀ ju bí ẹ ṣe lérò lọ. Ẹ finú wo ara yín ní ọjà àgbáyé tó kún fún ariwo, kì í ṣe pẹ̀lú ata àti àwọn ohun ìrántí, bí kò ṣe pẹ̀lú àwọn owó láti gbogbo ayé!
Kí ni forex?
Forex, tó jẹ́ ìkékúrú fún “ìpàrọ̀ owó orílẹ̀-èdè òkèèrè,” jẹ́ ìlànà ríra àti títà onírúurú owó lásán. Ó jẹ́ ọjà ìṣúná tó tóbi jù lọ, tó sì ní ìgbòkègbodò jù lọ ní àgbáyé, pẹ̀lú trílíọ̀nù àwọn dọ́là tí a ń ṣòwò lójoojúmọ́.
Kí ló dé tí ọjà forex fi wà?
Ẹ ro pé ilé-iṣẹ́ ará Amẹ́ríkà ni yín, tí ẹ fẹ́ ra àwọn ọjà láti ọ̀dọ̀ olùṣelọ́pọ̀ ará Ṣáínà. Ẹ gbọdọ̀ san owó fún wọn ní Chinese Yuan, ṣùgbọ́n US Dollars nìkan ni ẹ ní. Ibẹ̀ ni ọjà forex ti wọlé. Ó jẹ́ nẹ́tíwọ́ọ̀kì àgbáyé ti àwọn báńkì, àwọn bírókà àti àwọn ilé-iṣẹ́ tó ń ṣèrànwọ́ láti yí owó kan padà sí òmíràn.
Ìpàrọ̀ yìí ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo, káàkiri ayé, ó sì ń jẹ́ kí ìṣòwò àti ìgbòkègbodò owó àgbáyé máa lọ geere.
Báwo ni ìṣòwò forex ṣe ń ṣiṣẹ́?
Nítorí ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní, ìṣòwò forex wà fún gbogbo ènìyàn nípasẹ̀ àwọn pèpéle orí ayélujára bíi Deriv. Èrò pàtàkì rẹ̀ nìyí:
- Àwọn owó máa ń wà ní méjì-méjì: Ẹ máa ń ṣòwò owó kan sí òmíràn nígbà gbogbo, bíi Euro sí US Dollar (EUR/USD) tàbí British Pound sí Japanese Yen (GBP/JPY).
- Ẹ máa ń ṣe àsọtẹ́lẹ̀: Ṣé owó kan yóò lágbára sí i tàbí yóò rẹlẹ̀ sí òmíràn?
- Ẹ máa ń rà tàbí ta: Tí ẹ bá rò pé Euro yóò gòkè sí Dollar, ẹ “rà” pair EUR/USD. Tó bá gòkè lóòótọ́, ẹ ó tà ní iye tó ga jù, ẹ ó sì rí èrè. Tó bá sì lọ sílẹ̀, ẹ lè pàdánù. Ẹ tún lè ṣe ìdàkejì rẹ̀: ẹ tà ná, kí ẹ sì tún rà padà ní iye tó kéré jù.
Kí ló dé tí ẹ fi máa ṣòwò forex?
Nítorí náà, kí ló mú kí ìṣòwò forex gbajúmọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Àwọn ìdí díẹ̀ nìyí:
- Ìgbòkègbodò 24/5: Forex máa ń ṣí fún wákàtí 24 ní ọjọ́ kan, ọjọ́ márùn-ún láàárín ọ̀sẹ̀. Ẹ lè ṣòwò nígbàkúùgbà tó bá bá àkókò yín mu.
- Ó rọrùn láti wọlé àti jáde: Ọjà tí owó ti ń yí lọ geere ni, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé àwọn olùrà àti olùtà wà nígbà gbogbo. Èyí mú kí ó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ àti láti parí àwọn ìṣòwò.
- Oríṣiríṣi ìṣòwò: Forex lè ṣàfikún àkójọ ìṣòwò yín pẹ̀lú àwọn ìpín ìdókòwò tàbí àwọn ẹ̀ka dúkìá mìíràn.
Quiz
Kí ni ànímọ́ pàtàkì kan ti ìṣòwò Forex?


