Ìpìlẹ̀ àwọn Forex pair
Ẹ̀kọ́ yìí fún àwọn olùbẹ̀rẹ̀ ń darí yín la àwọn ìpìlẹ̀ ìṣòwò Forex kọjá.
Nínú ayé ìṣòwò forex, òye àwọn ìpìlẹ̀ ṣe pàtàkì fún àwọn oníṣòwò tuntun. Ọkàn ìṣòwò forex ni àwọn currency pair, tí ń jẹ́ kí ìparọ́ owó ṣeéṣe, tí ó sì ń jẹ́ kí àwọn oníṣòwò lè ṣe ìfojúsọ́nà lórí ìyípadà iye owó. Ẹ̀kọ́ yìí yóò ṣàlàyé àwọn forex pair, yóò túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì, yóò sì ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìgboyà sí i nínú ṣíṣòwò àwọn ohun ìṣòwò ìnáwó pàtàkì wọ̀nyí.
Kí ni Forex Pairs?
Forex pair jẹ́ owó méjì tó yàtọ̀ síra, níbi tí a ti ń sọ iye owó kan ní ìbámu pẹ̀lú èkejì. Fún àpẹẹrẹ, nínú currency pair EUR/USD, Euro (EUR) ni owó ìpìlẹ̀ (base currency), US Dollar (USD) sì ni owó ìfòdiwọ̀n (quote currency). Nígbà tí a bá sọ iye pair náà ní 1.0697, ó fi hàn pé Euro kan dọ́gba pẹ̀lú $1.0697.
Gbogbo ìṣòwò nínú forex ní ìgbésẹ̀ méjì: nígbà tí ẹ bá ra currency pair, ẹ ń ra owó ìpìlẹ̀ ní àkókò kan náà tí ẹ ń tà owó ìfòdiwọ̀n. Ní òdìkejì, tí ẹ bá tà pair náà, ẹ ń tà owó ìpìlẹ̀, ẹ sì ń ra owó ìfòdiwọ̀n. Òye ìlànà ìparọ́ yìí ṣe pàtàkì fún lílọ kiri ọjà forex lọ́nà tó múná dóko.
Òye nípa Pips
Pips, tàbí “percentage in points,” ni ìyípadà iye owó tó kéré jù lọ nínú currency pair, tí a sábà máa ń fi ipò decimal kẹrin ṣàfihàn. Ṣùgbọ́n, fún àwọn yen pair bíi USD/JPY, a ń wọn pips ní ipò decimal kejì. Fún àpẹẹrẹ, tí EUR/USD pair bá yí láti 1.2050 sí 1.2051, ìyẹn jẹ́ ìgbéga 1 pip.
Pips ṣe pàtàkì nítorí wọ́n ń ràn yín lọ́wọ́ láti wọn ìyípadà iye owó àti láti fojú díwọ̀n èrè tàbí àdánù tó ṣeéṣe nínú àwọn ìṣòwò yín. Jíjẹ́ ògbóǹtarìgì nínú ìṣirò pip lè mú kí ìṣòwò yín péye sí i, kí ó sì jẹ́ kí ìṣàkóso ewu dára sí i.
Àwọn Lot Size
Nínú ìṣòwò forex, a ń pe ìwọ̀n ìṣòwò yín ní lot. Lot size pàtàkì mẹ́rin ló yẹ kí ẹ mọ̀:
- Standard Lot: 100,000 unit ti owó ìpìlẹ̀.
- Mini Lot: 10,000 unit ti owó ìpìlẹ̀.
- Micro Lot: 1,000 unit ti owó ìpìlẹ̀.
- Nano Lot: 100 unit ti owó ìpìlẹ̀.
Yíyan lot size tó yẹ ṣe pàtàkì nítorí ó ní ipa taara lórí ewu tí ẹ ń kó. Àwọn lot tó tóbi lè mú èrè tó pọ̀ wá, ṣùgbọ́n wọ́n tún ní ewu tó pọ̀ sí i. Ní òdìkejì, àwọn lot kéékèèké ń jẹ́ kí ẹ ṣòwò pẹ̀lú ìṣọ́ra jù.
Ìparí
Òye ìpìlẹ̀ àwọn forex pair, ìyípadà pip, àti lot size jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ ìṣòwò yín. Pẹ̀lú ìmọ̀ yìí, ẹ ti ṣe tán dáadáa láti lọ kiri ọjà forex pẹ̀lú ìgboyà. Bí ẹ ṣe ń tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò yín, ẹ rántí pé àwọn ọgbọ́n ìṣòwò, ìṣàkóso olú-owó àti ìbáwí ara ẹni jẹ́ àwọn ohun pàtàkì fún àṣeyọrí ìgbà pípẹ́ nínú ìṣòwò forex.
A fi tayọ̀tayọ̀ rọ̀ yín láti ṣàwárí ìṣòwò forex lórí àwọn pèpéle Deriv, kí ẹ sì lo àwọn èrò tí ẹ̀kọ́ yìí bò láti kọ́ ìpìlẹ̀ tó fìdí múlẹ̀. Ẹ ṣòwò ní àṣeyọrí!
Quiz
Kí ni forex pair?
Kí ni pip dúró fún nínú ìṣòwò àwọn owó orílẹ̀-èdè?
Ìwọ̀n lot wo ni ó dúró fún ẹyọ 10,000 ti owó ìpìlẹ̀?


